Àdàkọ:Use Nigerian English
Kamorudeen Adekunle Adedibu Listen jé sínátọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò gúúsù Ọ̀yọ́ fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó dé orí ipò ní ọjọ́ 29 oṣù kaàrún ni ọdún 2007. Ó jé ọmọ ẹgbẹ́ alábùradà People's Democratic Party (PDP).[1]
Adedibu jé ọmọ bíbí inú àgbà olóṣèlú kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Lamidi Adedibu.[2] Lẹ́yìn tí ó dé orí àga àwọn aṣòfin àgbà, wọ́n fi jẹ alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé-iṣẹ́ (committees on industry), ìgbìmọ̀ ìṣọ̀kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ará ìlú àti ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀jọba (Federal character & Inter-Goverment affairs), ìgbàni-síṣẹ́ (Employment), òṣìṣẹ́ àti àbájáde iṣẹ́ (Labour & productivity), ètò ìdáàbòbò àti àwọn ọmọ ogun (Defence & Army), pẹ̀lú ètò ìròyìn àti ọ̀nà ìbániṣọ̀rọ̀ (Information and Media).[1] Ní ààrin ṣáà àgbéyẹ̀wò àwọn sínátọ̀ ní oṣù kaàrún, ọdún 2009, ìwé ìròyìn ThisDay jé kí a mọ̀ pé ó ṣe àtìlẹyìn fún àbá òfin ìdàgbàsókè àti ìdàsílẹ̀ ilé-iṣẹ́ (Nigeria Industrial Development Authority Establishment Bill), ó sì tún ṣe àtìlẹyìn fún àwọn àbá mìíràn.[3] Nínú ìfòròwánilẹ́nuwò oṣù kaàrún ọdún 2009, ó fi àìdùnnú nípa ipò tí orílẹ̀-èdè rẹ wà, tó sì ń ṣọ́ pé onírúurú ìṣòro ní ó sí kù tí yóò dojú kọ. Ó fẹ̀sùn àìsòótọ́ àti àìní àfojúsùn kàn àwọn àgbà òṣèlú.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
Itokasi