Smart AdeyemiSmart Adéyẹmí (tí a bí ní Ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù Kẹjọ ọdún 1960) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria láti ìpínlẹ̀ Kogí. Ìlà kàkà rẹ̀ gẹ́gẹ́ òṣèlúSínétọ̀ Smart Adéyẹmí ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin-àgbà níbi tí ó ti ṣojú ẹkùn ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogí títí di ọdún 2015 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party. Sínétọ̀ Dino Mélayé tí ẹgbẹ́ All Progressives Congress ló borí rẹ̀ nínú ìdìbò náà. Nígbà tí ó di ọdún 2019, Smart Adéyẹmí tún díje ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ṣùgbọ́n lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Dino Mélayé tí ó jẹ́ aṣojú ẹgbẹ́ PDP ló tún borí rẹ̀ nínú ìdìbò náà. [1] [2] Láìpẹ́ yìí, ilé-ẹjọ́ da ìbò tó gbé Dino Mélayé wọlé nù, ó sìn pàṣẹ kí wọ́n ṣe àtúndìbò mìíràn. Ìdìbò náà ń lọ lọ́wọ́ ni ìpínlẹ̀ Kogí.[3] [4] Lẹ́yìn àtúndì ìbò náà, Smart Adéyẹmí ló wọlé gẹ́gẹ́ bí Aṣòfin-àgbà láti ṣojú apá ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogí. [5][4] Àwọn Ìtọ́kasí
|