Ahmad Ibrahim Lawan GCON[1] (tí a bí ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù kìíní, ọdún 1959) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ọ̀jọ̀gbọ́n, tí ó sì ti sin ìlú gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ tí ìgbìmọ̀ sẹ́náàtì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 2019. Òun ni aṣojú senatorial district ní apá Àríwá ilẹ̀ Yobe. Ó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ All Progressives Congress.
Olùkọ́ àgbà ní Fáṣítì kan ni Gashua ni Lawan, wọ́n sì kọ́kọ́ yàn án sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọdún 1999 láti jẹ aṣojú àgbègbè Bade/Jakusko Constituency gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ All Nigeria People's Party. Wọ́n tún Lawan yàn ní ọdún kí ó tó lọ díje dupò Sẹ́nátọ̀ ní ìlú Yobe, tí ó sì wọlé ní ọdún 2007.[2] Lẹ́yìn tí wọ́n tún un yàn ní ọdún 2011, 2015, àti 2019, (gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ All Progressive Congress) wọ́n yán Lawan láti jẹ Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
Wọ́n bí Lawan ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kìíní, ọdún 1959 ní Gashua, tó jẹ́ apá Àríwá ilẹ̀ Nàìjíríà nígbà ìsìnrú àwọn aláwọ̀ funfun. Ó parí ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ilé-ìwé Sabon Gari, ní Gashua ní ọdún 1974 àti ilé-ìwé gírámà ní Government Secondary School, Gashua ní ọdún 1979 kí ó tó gboyè ní University of Maiduguri ní ọdún 1984. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Fáṣítì, ó sin orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Benue kí ó tó gboyè masters ní ng from the Ahmadu Belloàti oyè ọ̀jọ̀gbọ́n ní ng/GIS from Cranfieldní ọdún iversàti in 1. espectively.[3][4]
Àwọn Ìtọ́kasí