Àwọn Ẹ̀gbá jẹ́ ẹ̀ka ẹ̀yà Yorùbá ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọn wá láti àárín ìpínlẹ̀ Ògùn tí í ṣe Ogun Central Senatorial District.
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ Ẹ̀gbá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àriyànjiyàn nínú. Ìtumọ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀ le wáyé látara ọ̀rọ̀ Ẹ̀gbálugbó, tó túmọ̀ sí alárìnkiri rìn sínú igbó. Èyí sì lè jẹ mọ́ ìtàn tó fi yé wa pé àwọn ará Ẹ̀gbá wá láti Ilú-ọba Ọ̀yọ́, sínú igbó Ègbá, tí ó sì bí ìlú Abẹ́òkúta lónìí. Àwọn "Egbalugbo" wà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbáluwẹ tàbí Ẹ̀gbálodó, tí ó túmọ̀ sí alárìnkiri rìn sẹ́bàá odò, tí wọ́n sì padà gẹ́ kúrú sí "Ẹ̀gbádò", èyí tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìtumọ̀ mìíràn tó tún rọ̀ mọ́ ìlú Ẹ̀gbá yìí tún le jẹ́ Ẹsẹ̀gbá, èyí tí ń ṣe orúkọ olóyè tó darí àwọn ará Ẹ̀gbá sí agbègbè tí wọ́n wà lọ́wọ́lọ́wọ́.[1][2]
Ìtàn
Àwọn ọmọ ẹ̀gbá tó fìgbà kan wà lábé Ilú-ọba Ọ̀yọ́ gba òmìnira lẹ́yín tí Ọ̀yọ́ pín ní ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún.[3] Ogun tí wọ́n jà pẹ̀lú àwọn ará Dahomey, tí wọ́n sì jẹ́ olúborí latàri ìdábòbò tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ Òkè Olúmọ ló bí ìṣẹ̀dálè ìlú Abẹ́òkúta, èyí tó túnmọ̀ sí "abẹ́ òkuta".
Ẹ̀gbá pín sí ẹ̀ka mélọ̀ó kan, àwọn ni; Ake, Owu, Oke Ona, àti Gbagura, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ọba tirẹ̀. Lásìkò ìṣèjọba àwọn aláwọ̀ funfun, àwọn aláwọ̀-funfun yìí mọ Alake gẹ́gé bíi olórí gbogbo ìletò tó wà ní Ẹ̀gbá. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, oyè náà ti di oyè Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá. Oyè àwọn ọba ẹ̀ka yòókù ní Ẹ̀gbá ni Alake ti ìlú Egba, Osile ti Oke Ona, Agura ti Gbagura, àti Olowu ti Owu.
Ó pọn dandan láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé ìlú náà wà ní agbègbè òkè Olúmọ tẹ̀lẹ̀, tí ó wà ní agbègbè Ikija/Ikereku ti Oke Ona, ní Ẹ̀gbá. Jagunna ará Itoko, tó jé ọ̀kan lára àwọn olóyè Oke Ona, ni olú-awo òkè Olúmọ.
Ìlú Ègbá ni Henry Townsend fìgbà kan gbé, ibẹ̀ sì ni ilé ìwé-ìròyìn àkọ̀kọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ní Nàìjíríà tó ní orin ìyìn.
Orin ìyìn Ẹ̀gbá
Lori oke o'un petele
Ibe l'agbe bi mi o
Ibe l'agbe to mi d'agba oo
Ile ominira
Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo
Abeokuta ilu Egba
N ko ni gbagbe e re
N o gbe o l'eke okan mi
Bii ilu odo oya
Emi o f'Abeokuta sogo
N o duro l'ori Olumo
Maayo l'oruko Egba ooo
Emi omoo Lisabi
E e
Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo
Emi o maayo l'ori Olumo
Emi o s'ogoo yi l'okan mi
Wipe ilu olokiki o
L'awa Egba n gbe
Egbè: Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo; Maa yo, maa yo, maa yo o; l'Ori Olumo