Túndé Kèlání ni wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejì, ọdún 1948 (born 26 February 1948),jẹ́ gbajú gbajà olùgbéré jáde,ayàwòrán, adarí eré àti Onímọ̀ nípa Sinimá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ni TK.[1] Ohun tí TK mọ̀ọ́ṣe ju ni kí ó gbe eré tí ó polongo àṣà àti ìṣe Yorùbá tí ó nítàn tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú, àkọsílẹ̀, ẹ̀kọ́, àti ìmóríwú, tí ó si tún ń dà ní lára ya nínú àṣà Yorùbá jáde nílẹ̀ Nàìjíríà Yorùbá.[2]
Ìgbé ẹwà Yorùbá rẹ̀ ga
Tk tún ma ń gbìyànjú nínú ọ̀pọ̀ eré orí ìtàgé tí ó ba gbé jáde láti ṣàmúlò àṣàyàn èdè Yorùbá yó dángájíá láàrín ìtàn eré aládùn rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Bí àpẹrẹ, nínú sinimá : Kò ṣé Gbé, Ólekú, Thunder Bolt (Ẹdun Àrá), The Narrow Path, White Handkerchief, Màámi àtiDazzling Mirage.[3][4]
Ìbẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀
Nígbà èwe rẹ̀, wọ́n mu lọ sí Abẹ́òkúta, láti máa gbé pẹ̀lú àwọn òbí òbí rẹ̀. Àwọn ọgbọ́n , ìmọ̀ Òun òye tí ó rí kójọ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí óbí rẹ̀ tí wọ́n kún fọ́fọ́ nibi àṣà Òun ìṣe Yorùbá yí àti ìrírí rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ tí ó ní London Film School nibi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ni ó fun ní ànfàní láti wà ń ipò tí ó wà lónìí. [5][6][7][8]