Ernest Adégúnlé Oládéìǹdé Shónèkàn, (ọjọ́ kẹẹ̀sán, oṣù Ebi ọdún1936 ní Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà) jẹ́ agbejọ́rò ará ilẹ̀ Nàìjíríà. Shónékà jẹ́ Ààrè ilè Nàìjíríà fún ìgbà díẹ̀ láti ọjọ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́jọ, ọdún 1993 títí dé ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kọkànlá, ọdún 1993 tí ọ̀gágun Sani Abacha fipa gbà joba lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n fun ní oyè Abese tí ilẹ Ègbá láti 1981 pẹ̀lú àwọn oyè mìíràn[1].
Shónẹ́kàn ti jẹ́ alága àti olùdarí United African Company of Nigeria ( èyí tí ó rọ́pò The Niger Company) Ilé-iṣẹ́ tí ó gbòòrò tí ó sì jẹ́ pé òun ni ilé-iṣẹ́ Áfíríkà tí ó gbòòrò jù ní ilẹ̀ Sub-Saharan Africa.[2]
Ìgbé ayé rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
Ọjọ́ kẹẹ̀sán, oṣù Ebi ọdún 1936 ní wọ́n bí Shónẹ́kàn ní ìlú Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ̀ bí.[3]. Ilé-ìwé CMS Grammar School àti Igbobi College ni Shónẹ́kàn lọ.[4] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ òfin ní University of London, wọ́n sì pè é sí iṣẹ́. Lẹ́yìn náà ni ó tún lọ sí Harvard Business School.[5]
Wàhálà tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rìpọ́bíkì kẹ́ta.
Ní oṣù Ṣẹrẹ, ọjọ́ kejì, ọdun 1993, Shonekan kọ́kọ́ di olórí ìgbìmọ̀ ìyípadà àti olórí ìjọba lábẹ́ Ibrahim Babangida. Nígbà náà ìgbìmọ̀ ìyípadà jẹ́ ìpele tó kẹ́yìn nínú gbígbé agbára fún olórí tí wọ́n yàn ní Rìpọ́bíkì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kẹ́ta.[6] Ní oṣù Ògún, ọdún 1993, Babangida kọ̀wẹ́ fipò sílẹ̀, nípa títẹ̀lé ìdìbò June 12. Ó bọwọ́ lú òfin tí ó fi ìdí ìjọba-fìdí-hẹ múlẹ̀ tí Shonekan darí lẹ́yìn tí wọ́n búra fun gẹ́gẹ́ bí olórí orilẹ̀-èdè.[7][8]
Itokasi