Ebbe Bassey
Ebbe Bassey jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati Amẹ́ríkà tí a yàn fún àmì-ẹ̀yẹ Africa Movie Academy Award kan fún tí òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn nípasẹ̀ ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bi "Maa Dede" nínu Ties That Bind ní ọdún 2011. Iṣẹ́-ìṣeBassey ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ati ti Amẹ́ríkà, lára wọn ni Doctor Bello, Mother of George, NYPD Blue, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ti rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ látàrí ipa rẹ̀ nínu eré Ties That Bind.[1] Ní ọdún 2012, ó kéde rẹ̀ wípé òun fẹ́ gbé eré ṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Saving Father, léte àti la àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ nípa níní àti gbígbé ayé pẹ́lú kòkòrò àrùn AIDS.[2] Níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2013, wọ́n tún yan Bassey gẹ́gẹ́ bi òṣèré tó n ṣe àtìlẹyìn tó dára jùlọ nínu fiimu.[3] Ní ọdún 2012 bákan náà, Bassey kópa nínu fiimu Turning Point. fiimu náà ṣì gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Nollywood and African Film Critics Awards, èyí tí ó wáyé ní Amẹ́ríkà.[4] Ní ọdún 2016, ó kó ipa "Imani" nínu fiimu Tomorrow Ever After, ó sì ní àwọn èsì àtúnyẹ̀wò rere fún ipa rẹ̀ nínu fiimu náà.[5][6] Bassey pẹ̀lu Richard Mofẹ́-Damijo ni wọ́n jọ ṣètò ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2016 ní Ilé-iṣẹ́ tó wà fún eré ṣíṣe, Ilé-iṣẹ́ BMCC Tribeca Performing Arts Center ní ìlu New York.[7] Ìgbé ayé rẹ̀A bí Bassey ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n ó lo àwọn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ní ìlu Calabar ṣááju kí ó tó padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti máa gbé níbẹ̀.[8] Ó ti ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lu Mark Manczuk. Àwọn Ìtọ́kasí
Àwọn ìtakùn Ìjásóde
|