The White Handkerchief
The White Handkerchief jẹ́ fíìmù Nàìjíríà kékeré kan tó jáde ní ọdún 1998, èyí tí Tunde Kelani jẹ́ olùdarí rẹ̀, tí ó sì ṣàfihàn àwọn òṣèré bí i Yemi Komolafe, Yemi Shodimu, àti Khabirat Kafidipe.[1] Fíìmù yìoí jẹ́ àyọkúrò ìwé ìtàn-àròsọ ti Bayo Adebowale, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ The Virgin.[2][3] Àhunpọ̀ ìtàn ní ṣókíFíìmù náà dá lórí ìtàn ọ̀dọ́bìnrin abúlé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Awero, tí Sola Asedeko ṣe, tí ó pàdánù ipò wúńdíá rẹ̀ látàrí ìfipábánilòpọ̀ kí ó tó pàdé olólùfẹ́ ìgbà èwe rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odejimi, ẹni tí ó pinnu láti fẹ́ ẹ. Odejimi gbọ́dọ̀ lo aṣọ funfun, kí ó ba lè dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ó bá Àwèró ní wúńdíá ní alẹ́ ìgbéyàwó wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣà ilẹ̀ náà. Inú Odejimi bàjẹ́ nígbà tí kò sí ẹ̀jẹ̀ lórí aṣọ funfun náà, èyí sì fa ogun láàárín àwọn ará abúlé Àwẹ̀ró àti Odejimi.[4][5] Àwọn akópa
Àwọn ìtọ́kasí
Information related to The White Handkerchief |