Oúnjẹ àwọn ará ilẹ̀ Mali jẹ́ èyí tí ó kó ìrẹsì àti jéró sínú gẹ́gẹ́ bíi àwọn ohun èlò oúnjẹ Mali, àṣà oúnjẹ tó rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn irúgbìn.[1][2] Àwọn irúgbìn tí a máa ń pèsè pẹ̀lú àwọn ọbẹ̀ tí a ṣe láti ara àwọn ewébẹ̀ tí ó ṣe é jẹ̀, gẹ́gẹ́ bí spinach, ọ̀dùnkún tàbí baobab, pẹ̀lú ọbẹ̀ tòmátò àti ẹ̀pà. Àwọn oúnjẹ tí a le jẹ pẹ̀lú àwọn ẹran tí a yan gẹ́gẹ́ bíi, ẹran adìẹ, ewúrẹ́, àgùntàn, tàbí ẹran màálù.[1][2]
Oúnjẹ àwọn Malian yàtọ̀ láti ìletò kan sí ìletò mìíràn.[1][2] lára àwọn oúnjẹ ẹkùn ìwọ-oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn oúnjẹ mìíràn tí wọ́n tún gbajúgbajà ní Mali ni fufu,Dibi, Jollof rice, àti maafe