Fufu (tàbí fufuo, foofoo, foufou) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ounjẹ tí ó gbajúmò ni ìwọ oòrùn Áfríkà. Pàá pàá julọ Ghana àti Nàìjíríà,[1] Wọn tún ma ń se ní àwọn orílẹ̀-èdè bi Sierra Leone, Guinea, Liberia, Cote D'Ivoire, Benin, Togo, Cameroon, the Democratic Republic of Congo, the Central African Republic, the Republic of Congo, Angola àti Gabon.[2] Oríṣi ọ̀nà ni wọn lè gbà se Fufu.
Fufu ni ilẹ̀ Áfríkà
Àwọn oníṣòwò orílè-èdè Portuguese ni wọn mú ẹ̀gẹ́ wá sí ilè Áfríkà láti orílè-èdè Brazil ní 16th century.[3] Ní Ghana, fufu(tí wọn tún mọ̀ sí fufuo), funfun, ó sì má ń lè (tí wọn kò bá fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ sára ẹ̀gẹ́ náà tí wọ́n bá ń gun lódó). Ọ̀nà tí wọ́n fi ń jẹ fufu ni bíbu díè sowo tí wọ́n ó sì yi mowo láti mú ara rẹ̀ dán, wọ́n ó ti bo ọbẹ̀ kí wọ́n ó tó jẹ́.
Fufu Nàìjíríà
Ní Nàìjíríà, fufu tàbí akpu jẹ́ oúnjẹ tí ó gbajúmò, tí wọ́n sì ma ń fi ẹ̀gẹ́ se.[4][5][6] Akpu(bí àwọn igbo se ma ún pè é) jẹ́ oúnjẹ tí wọ́n ma ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ se, wọ́n sì ma ún sábà jẹ pẹ̀lú ọbẹ̀ egusi.
Àwon Ìtókasí
- ↑ "5 Popular Swallows Eaten By Ghanaians". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-03.
- ↑ Victoria, Akinola (2022-04-24). "5 Nigerian meals that have similar versions across African countries". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-03.
- ↑ "A review of cassava in Africawith country case studies on Nigeria, Ghana,the United Republic of Tanzania, Uganda and Benin". www.fao.org. Retrieved 2018-04-22.
- ↑ "cassava".
- ↑ "HOW TO MAKE WATER FUFU FROM SCRATCH - CASSAVA FUFU". Precious Core (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-14. Retrieved 2022-05-12.
- ↑ "How To Make Fufu From Scratch (Nigerian Fufu)". My Active Kitchen (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-17. Retrieved 2022-05-12.