King of Thieves (Agẹṣinkólé) jẹ́ ọ̀kan lára àọn fíìmù orílẹ̀-èdẹ̀ Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2022, èyí tí Femi Adebayo ṣàgbéjáde, tí Tope Adebayo àti Adébáyọ̀ Tìjání sì darí.[2][3] Ọ̀pọ̀ àwọn ògbóǹtarìgì òṣèré bí i Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Toyin Abraham, Broda Shaggi, Adebowale "Debo" Adedayo aka Mr Macaroni, Lateef Adédiméjì, àti Ibrahim Chatta ló kópa nínú fíìmù náà.[4][5] Fíìmù ìgbaanì ajẹmọ́-ìtàn-akọni tí wọ́n fi èdẹ̀ Yorùbá ṣe jẹ́ èyí tí ilé-iṣẹ́ Femi Adebayo tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Euphoria360 gbé jáde. Ilé-iṣẹ́ Níyì Akínmọláyàn tí orúkọ rè ń jẹ́ Anthill studios sì ni aṣèrànwọ́-ìṣàgbéjáde. Wọ́n ṣàfihàn àkọ́kọ́ fún fíìmù náà ní ọjọ́ 4 oṣù kẹrin, ọdún 2022, tó wáyé ní IMAX Cinemas, ní Lekki, Ìpínlẹ̀ Èkó.[6] Fíìmù náà wọ orí sinimá ní ọjọ́ 8 oṣù kẹjọ, ọdún 2022 bákan náà.[7]
Àṣàyàn àwọn akópa
Ìṣọníṣókí
"King of Thieves" (Ògúndábède) dá lórí ìtàn ìlú ọlọ́lá kan tí wọ́n ń pè ní Ajeromi. Ayé ní ìlú Ajeromi tòrò, àlàáfíà jọba, ó sì tún kún fún ọlá. Àmọ́ ìfọ̀kànbalẹ̀ ìlú náà doríkodò nígbà tí Ageṣinkólé, tó jẹ́ olè ọlọ́ṣà kan bẹ̀rẹ̀ sí ní dààmú ìlú náà.
Làtàrí ìpinnu ìlú láti dáàbò bo àlàáfíà ìlú wọn, wọ́n pawọ́ pọ̀ láti gbógun Agesinkole yìí. Lára ìgbìyànjú tí wọ́n sà ni àwọn ògbójú ọdẹ, àjẹ́ tó lágbára, àti àwọn ògbóǹtarìgì oṣó, tí wọ́n parapọ̀ láti sa gbogbo ipá àti agbára wọn láti kojú ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ìlú wọn.[9]
Ìṣàfihàn
Ìṣàfihàn àkọ́kọ́ tí fíìmú yìí wáyé ní ọjọ́ 4, oṣù kẹrin, ọdún 2022, ní IMAX Cinemas, Lekki, ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Àkọ́lé ìṣàfihàn náà ni ajẹmọ́-ìtàn-akọni-tí-ìgbaanì àti eléwu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ ló sì yẹ́ ayẹyẹ náà sí, tí wọ́n sì múra ní ìbámu pẹ̀lú àkọ́lé náà.[10] Lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tí wọ́n wà níbi ayẹyẹ náà ni Tade Ogidan, Tunde Kelani, Iyabo Ojo, Antar Laniyan, Segun Arinze, Mercy Aigbe, Dayo Amusa, Eniola Ajao, Denrele Edun, Muyiwa Ademola àti bẹ́ẹ̀ béẹ̀ lọ.[11] Ilé-iṣẹ́ StarTimes, èyí tí Femi Adebayo jẹ́ aṣojú fún gba Femi Adebayo lálejò, wọ́n sì kí i kú oríire fún ìṣá̀gbéjáde fíìmù rè. Ìgbàlejò yìí wáyé ní sinimá Silverbird, ní Ikeja City Mall.[12]
Awards and nominations
Year
|
Award
|
Category
|
Recipient
|
Result
|
Ref
|
2023
|
Africa Magic Viewers' Choice Awards
|
Best Actor In A Drama, Movie or TV Series
|
Femi Adebayo
|
Wọ́n pèé
|
[13][14]
|
Best Art Director
|
Wale Adeleke
|
Gbàá
|
Best Picture Editor
|
Sanjo Adegoke
|
Wọ́n pèé
|
Best Sound Track
|
Adam Songbird & Tolu Obanro
|
Wọ́n pèé
|
Best Make Up
|
Francisca Otaigbe
|
Wọ́n pèé
|
Best Writer
|
Yinka Laoye
|
Wọ́n pèé
|
Best Overall Movie
|
Femi Adebayo
|
Wọ́n pèé
|
Best Director
|
Adebayo Tijani & Tope Adebayo
|
Wọ́n pèé
|
Àwọn ìtọ́kasí