Kadiri Ikhana (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kọkànlélógbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1951) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù,Kano Pillars nígbà kan rí, tí ó wá di akọ́nimọ̀ọ́gbà bọ́ọ̀lù-àfẹségbá ọmọ Nigeria.
Iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù
Ikhana gbá bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá jẹun pẹlu ikọ̀ Bendel Insurance, tí wọ́n sìn gba ife-ẹ̀yẹ líìgì àgbábuta lọ́dún 1978 àti 1980.[3]
Ikhana wà lára ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nigeria tí wọ́n ṣojú orílẹ̀-èdè náà láti gba ìdíje-amúnipegedé fún ìdíje ife àgbáyé FIFA tí wọ́n gbá díje nínú ìdíje Olympics lọ́dún 1980.[1] Ó wà lára ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nigeria tí wọ́n gbé igbá orókè nínú ìdíje, 1980 African Cup of Nations.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá
Ikhana ti ṣiṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún oríṣiríṣi ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àdání, lára wọn ni; El-Kanemi Warriors F.C., BCC Lions F.C., Kwara United F.C., Sunshine Stars F.C., Sharks F.C. àti Giwa F.C..[4]
Ikhana ni akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Enyimba International F.C. lórílẹ̀-èdè tí wọ́n gba ife-ẹ̀yẹ, African Champions League lọ́dún 2003.[5] Ọdún yìí náà ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá tí ó dára jù lọ.[5] In 2004, he was manager of the Nigerian men's Olympic team.[6]
Lẹ́yìn náà ó ṣiṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kano Pillars F.C., kí ó tó kọ̀wẹ́fipòsílẹ̀ lóṣù kaàrún ọdún 2008, pẹ̀lú ìbòsí ìwà àjẹbánu nínú àjọ eré-ìdárayá tí ó ké fún ìdí tí ó fi ṣe bẹ́ẹ̀.[5] He had led Kano Pillars to their first ever league title a day earlier.[7]
Wọ́n yàn án ní akọ́nimọ̀ọ́gbá àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-obìnrin tí orílẹ̀-èdè Nigeria lóṣù kẹrin ọdún 2012,[8] kí ó tó kọ̀wẹ́fipòsílẹ̀ lóṣù November, ọdún 2012.[9]
Ó ń ṣiṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nasarawa United F.C. títí di oṣù November 2013 nígbà tí ó pinnu láti ṣíwọ́ iṣẹ́ eré-ìdárayá.[10] Ó tún padà sí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Enyimba, tí ó sìn tún gba ife-ẹ̀yẹ líìgì àgbábuta kí ó tó tún dara pọ̀ mọ́ Shooting Stars S.C. lóṣù February ọdún 2016.[11] Ó tún padà sí ikọ̀ Kano Pillars lóṣù November ọdún 2016,[4][12] before being sacked in April 2017.[13]
Àwọn àṣeyọrí
Àṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù
- Pẹ̀lú Bendel Insurance
- Nigerian Premier League – 1979[3]
- Nigerian FA Cup – 1978, 1980[3]
- Pẹ̀lú Nigeria
- African Cup of Nations – 1980[3]
Àṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá
- Pẹ̀lú Enyimna
- Nigerian Premier League – 2015[11]
- CAF Champions League – 2003[5]
- Pẹ̀lú Kano Pillars
- Nigerian Premier League – 2008[7]
Àṣeyọrí aládàání
- Akọ́nimọ̀ọ́gbá tí ó dára jù lọ lọ́dún 2003[5]
Àwọn Ìtọ́kasí