Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 2020, jàmbá iná ló fa ìtúká aláriwo olóró ní èbúté ìlú Bèírùtù, tó jẹ́ olúìlú orílẹ̀-èdè Lẹ́bánọ́nù. Ìtúká aláriwo kejì lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tó ṣokùnfà ikú àwọn ènìyàn tó pọ̀ tó ẹ̀tà-dín-lẹ́wàá-lé-nígba, àwọn tó farapa tó ẹgbẹ̀fàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta, àwọn ohun ìní tó ṣòfò tó US$10 sí 15 billionu, ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ àwọn ènìyàn tó pọ̀ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún (300,000) di aláìnílé.[1]Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ nítorí 2,750 tonnes (3,030 short tons; 2,710 long tons) àmóníọ́mù onínáítirójiínì – tí agbára rẹ̀ tó 1.2 kilotons of TNT (5.0 TJ) – tí ìjọba Lẹ́bánọ́nù ti gbẹ́sẹ̀lé látọwọ́ ọkọ̀ ojú-omi akẹ́rù "MV Rhosus", tí wọ́n sì kó pamọ́ sí apá kan ní èbúté náà láì sí àbò àti ìṣọ́ra tó yẹ fún ọdún mẹ́fà.
Àwọn ìtọ́kasí