Àwọn ènìyàn Efik jẹ́ ẹ̀yà tí ó wà ní apá gúúsù Nàìjíríà, àti apá ìwọ̀ òórùn Cameroon. Ní Nàìjíríà, a lè rí àwọn ẹ̀yà Efik ní ibi tí ó jẹ́ Ìpínlẹ̀ Cross River àti Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom lóde òní. Èdè àwọn ènìyàn Efik ni Èdè Efik tí ó jé ọkàn lára àwọn ìdílé èdè Benue–Congo tí àkójọ èdè Niger-Congo.[5] Àwọn ènìyàn Efik ma ń pe ara wọn ní Efik Eburutu, Ifa Ibom, Eburutu àti Iboku.[6][7]