Àwọn wọ̀nyí ni àwòn Òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.
Òrìṣà tó ga jù
Ọlọ́run Elédùmarè ní orúkọ mẹ́ta tí Yorùbá má ń pèé, àwọn ni:
- Elédùmarè - Olùṣèdá ohun gbogbo.
- Ọlọ́run - Olù kápá ọ̀run.
- Ọlọ́fin - Olù sààmì láàrín ọ̀run àti Ayé
[1]
Àwọn òrìṣà tó níiṣe pẹ̀lú ìpín
- Ọ̀rúnmìlà - Ó jẹ́ òrìṣà ọlọ́gbọ́n, ìpín, àti arínú róde.
- Orí - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ ìṣèdá tàbí ìpín
Àwọn Òrìṣà Imọlẹ̀ tí ó jẹ́ akọ
- Ọbalú Ayé - Ó jẹ́ òrìṣ̀à tí ó rọ̀ mọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tí ó sì tún ma ń ṣe ìwòsan àjàkálẹ̀ àrùn.
- Erinlẹ̀ - Ó jẹ́ òrìṣà ìwòsàn, ó sì tún ma ń ṣe ìwòsàn àrùn. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó ma ń mú ìtura bá ènìyàn
- Èṣ̣ù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé oríta, ó jẹ́ òrìṣà ẹlẹ̀tàn, tí ó sì ma ń ṣeni ní jàmbá
- Ìbejì - Ó jẹ́ òrìṣà àwọn ọmọ méjì tí a bí papọ̀, ó ma ń fúni lọ́mọ.
- Kokou - Ó jẹ́ òrìṣà oní jàgídí-jàgan
- Ọbàtálá - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó mọ orí àti gbogbo ara tó kù fún ọmó ènìyàn. Ó jẹ́ òrìṣà ìmọ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ òrìṣà tí ó mọ́ kangá tí ó sì ma ń ṣe déédé
- Odùduwà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ṣẹ àwọn ọmọ Yorùbá kalẹ̀ sí ilé Ifẹ̀
- Ògún - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó rọ̀ mọ́ irin tàbí àgbẹ̀dẹ. Ó sì tún jẹ́ jagun jagun nígbà ayé rẹ̀
- Òrìṣà Oko - Ó jẹ́ òrìṣà tí Yorùbá ma ń lò láti fi ṣètò ohun ọ̀gbìn
- Ọ̀sanyìn - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń ṣòfófó fúni. ó lè gbé inú ilé tàbí inú oko
- Òṣùmàrè - Ó jẹ́ òrìṣà tó dàbí ejò tí ó ma ń ta àwọn àwọ̀ oríṣi méje sí ojú ọ̀run
- Ọ̀ṣọ́ọ̀sì - Ó jẹ́ òrìṣà tí wọ́n fi ń dẹ ọdẹ tàbí ro oko
- Ṣàngó, Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ma ń sán àrá látojú ọ̀run
Àwọn Òrìṣà Yorùbá tí ó jẹ́ abo
- ́Àjà - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ń gbé inú igbó tàbí aginjù, kò yàtọ̀ sí iwin, ó sì ma ń ṣe ìwòsàn.
- Ajé Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi tí ó ma ń ṣ̀àánú ènìyàn pẹ̀lú ọrọ̀.
- Ẹ̀fúùfù - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí ìjì tàbí atẹ́gùn.
- Mawu - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó níkàpá lórí Òòrùn àti Òṣup̀á.
- Ọ̀bà - Òrìṣà yí jẹ́ ìyàwó Ṣ̀àngó àkọ́kọ́ tí ó di omi
- Olókun - Ó jẹ́ òrìṣà omi.
- Ọ̀ṣun - Òrìṣà yí jẹ́ òrìṣà omi, tí o ́ní ṣe pẹ̀lú ìfé, ẹwà, àti owó.
- Ọya - Ó jẹ́ òrìṣà tí ó ní agbára láti dá ìjì, mọ̀nàmọ́ná, fífúni lówó, àti idán fún ọmọ́ ènìyàn
- Yemọja - Ó jẹ́ òrìṣà olú-odò tí ó ní agbára púpọ̀.
Àwọn ìtọ́ka sí
- ↑ "Awon asa ati orisa ile Yoruba in SearchWorks catalog". SearchWorks catalog. 2019-06-15. Retrieved 2019-07-02.