Obianuju Ekeocha
Obianuju Ekeocha /θj/, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Uju (a bi ní odun 1979), jẹ́ onímọ̀ Sáyẹ́nsì ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà tí ó ń gbé ní Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan.[2] Òun ni ọ̀lùdásílẹ̀ àti ààrẹ "Culture of Life Africa".[3][4] Ìtàn rẹ̀Ekeocha ń gbé ní orílẹ̀ èdè Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan[5] ẹ̀ka ibi tí ó ti ń síse ni ẹ̀ka àwọn tí ó ń wo ẹ̀jẹ̀ fún àìsàn, kòkòrò àti àwọn nkan míràn. Ní ọdún 2016, wón fun ní isẹ́ sí ilé ìwòsàn ní Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan. Ó jẹ́ ara ìjọ Kátólíìkì làti Ìpìlẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ayé rẹ̀ nígbà tí ó wà ní Nàìjíríà.[6] Ẹ̀kọ́ rẹ̀Obianuju lọ ilé-ìwé Federal Government Girls' College ti Owerri, kí ó tó tẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Yunifásítì ilẹ̀ Nàìjíríà, Nsukka, níbi tí ó ti gba àmì ẹyẹ Bachelor nínú ìmò Microbiology. Lẹ́yìn èyí ó lọ orílè-èdè Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan láti gbà àmì ẹyẹ master nínú ìmò Biomedical science ní Yunifásítì East London. Àwọn Ìtókasí
Information related to Obianuju Ekeocha |