kíni Madrasa? jé ìwé tí a ti owó Ebrahim Moosa tí ó jé onímò ìjìnlè nínú èsìn Islam tí ó sì jé olópolo pípé èdá. Ìwé yii je àkójopò ìtàn ayé, ìgbenuso, àyèwò èyà ènìyàn àti ìtàn ìgbà pípé tí ó sì n fún ni ní ìwòye gégé bíi ti eni tí ó wà nínú Deobandi madrasas nínú àdáyébá-ile kékeré ti India. A se àtèjáde rè ní ipasè ile-èkó gíga University of North Carolina Press ní osù kerin odún 2015.[1]
Àkópọ̀
Ìwé naa ni ipa merin, ti o si je àkójopò ìtàn ayé, ìgbenuso, àyèwò èyà ènìyàn àti ìtàn ìgbà. Ìdi gbòógi ìwé yìí ni lati fún àwon ènìyàn ní ìwòye eni tí ó wà nínú Deobandi madrasas nínú àdáyébá-ilè kékeré ti India.
Moosa ti se ìgbejade ìrírí rè odún méfà nínú ìsèse madrasa ní apá àkókó. Apá yìí se àsekágbá pèlú àwon àpeere nípa bí ìlànà tí ó bá òfin ti Hanafi mu se di lílò gégé bíi ìlòdì sí ìrònú tó nàn sàán nígbà ayé àwon amúnisìn l'ówó àgbà òmòwé Deobandi bìi Ashraf Ali Thanwi àti Muhammad Qasim Nanautawi. Apá kejì ni a pè ní Ìtàn àti ààyè rè, nínú èyi tí Moosa máa n lò bíi ìlànà ìtàn ìgbésí ayé láti fi owó ba ààyè àwùjo, òsèlú àti ìtàn ìgbà tí ó yí ìdásílè nétíwóòkì madrasa kà ní India àti Pakistan. Ó se àlàkalè ìyàtò ìtàn ìgbà ìdílé àti èsìn tí ó se ìrànwó fún ìdásílè àti ìdàgbà s'ókè Ahl-i Hadith, Barelwi àti àwon ilé-èkó Deobandi.
Moosa "fi ojú sí àwon àríyànjiyàn àti ìsesí tí ó ní se pèlú ìyà s'ótò àti kókó ìmò” nínú apá keta ìwé náà tí a pè ní Òsèlú Ìmò. Apá yíi ká'gbá pèlú títú àdìtú Islam àti eléka jè'ka Islam àti èko ìmò titun nípa bí a sé n se àwárí ìmò." Gégé bíi alátèjáde rè se se àlàyé rè, èko ìmò titun nípa Islam "ló pó mò èka gbòógì méjì", tí kò sì se ìyàsótò gbòógì kankan l'ààrin ìmò èko.
Apá kerin Madrasas ní ìwòye àgbáyé níí'se pèlú ìwòye òdì sí madrasas tí ayélujára ati móhùnmáwòrán dá sí'lè. Moosa se àsekágbá apá yii pèlu létà méjì: òkan sí àwon asòfin orílè-èdè Améríkà àti ìkejì sí àwon olùkó rè télè. Nínú létà àkókó, ó se àlàyé fún ìdádúró ètò ti díròònù àti àwon òfin ilè Améríkà míràn tí ó dojú ko àtúndá àwon àwùjo mùsùlùmì àti àwon àsà àti ìse Islam ìgbà pípé, àti nínú ìkejì, ó pa àrowà sí àwon olùkó rè láti se àwon àtúnse kan sí àwon ètò madrasa. Apá yìí tako ìwòye ti ayélujára àti òfin ìjoba sí madrasas, àti wípé "àdínkù tí ó n bá ìmòye àsà madrasa, àti àwon olusàkóso nínú madrasas tí ko ní ìtara tàbí tí kò ní òye tó kún tó lati darí àwon isé àtúnse."
Àtókasí
Ìwé ìtàn
Kíkà Síwájú
- Khan, Sabith (2019). "What Is a Madrasa? by Ebrahim Moosa (review)". Journal of Education in Muslim Societies (Indiana University Press) 1 (1): 66–68.