Joy Amechi Eze (tí wọ́n bí ní 23 April 1988) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó máa ń kópa nínú ìdíje eré sísá, tí irinwó mítà. Àkọsílẹ̀ ìdíje rẹ̀ tó dára jù ni èyí tó sá ní ìṣẹ́jú àáyá 51.20 nínú ìdíje 2007 All-Africa Games.
Ní ọdún 2006, ó gba àmì-ẹ̀yẹ onífàdá́kà nínú ìdíje 4x400 metres relay, ní 2006 Commonwealth Games àti 2006 World Junior Championships. Ní ìdíje 2007 All-Africa Games, ó gba àmì-ẹ̀yẹ onífàdákà ní 400 m àti 4x400 metres. Nínú ìdíje 2008 African Championships, ógbé ipò kẹfà nínú ìdíje 400 m, ó sì tún jáwé olúborí nínú ìdíje 4x400, tó fi gba àmì-ẹ̀yẹ oníwúrà.
Àwọn àṣeyọrí rẹ̀
Àwọn ìtọ́kasí