Ilokulo Omo Obinrin Ni Orile Ede Naijiria.(Girls Child Labour in Nigeria)

Ìlòkulò ọmọ obìnrin ní orílẹ èdè Nàìjíríà jẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ tó ń sẹlẹ̀ sí ọmọ obìnrin tó wà láàrin ọdún máàrún sí mẹ́rìnlá tó ń lọ́wọ́ sí akitiyan ọrọ̀ ajé yàtò sí ẹ̀kọ́ ìwé àti ̀igbà ìsinmi wọn[1]. Lílo ọmọbìnrin ní ìlòkulò ní Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti di ìwà Ìbàjẹ́ tó tànkálẹ̀ látàrí ọrọ̀ inú ilé [2] sùgbọ́́n àwọn okùnfà míràn bíi àseyọrí ètò ẹ̀kọ́, ìpele ẹ̀kọ́ òbí, ẹgbẹ́ aláàbárìn, ìbéèrè fún alábásisẹ́ nínú ilé àti òsìsẹ́ alábálòpọ̀, gbogbo eléyìí ló ń sokùn fa tí ìlòkulò ọmọ obìnrin se pọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà [3]. Láfikún, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwùjọ ìgbèríko àti mùsùlúmí ní ariwa orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,nígbàmíràn wọn a máa rán àwọn ọmọdé tàbí obìnrin ẹléhàá nísẹ́.[4]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọdébìnrin yìí a máa ṣiṣẹ́ gẹǵẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ nínú ilé, olùrànlọ́wọ́ ilé ìtajà, oníkiri ọjà lójú pópó. Lílo àwọn ọ̀dọ́mọdébìnrin nínú akitiyan ètò ọrọ̀ ajé ti fi wọ́n hàn sí ewu ìbálòpọ̀, àìrí ìtójú látọ̀dọ̀ òbí àti ìlòkulò.[5] Láfikún,iṣẹ wọn yìí kò lẹ́ẹ̀tó lábé òfin àti pé kò ní ànfààní kankan gẹ́gẹ́ bíi òṣìṣẹ́.

Ńi Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,àwọn okùnfà bíi òsì àti àìríṣẹ́ṣe òbí,ìsílo kúrò ní ìgbèríko sí ìlú, ìwọ̀n ẹbí tí ó tóbi,àwọn àsà bíi ìlóbìnrin púpọ̀ jẹ́ orírun fún ìlòkulò ọmọ, àwọn èyí tí ó jẹyọ láti àwùjọ, iye ènìyàn àti ọrọ̀ ajé.[6] Àwọn okùnfà míràn ni ilé ẹ̀kọ́ pínpín tó kéré, àìrí àyẹ̀wò àti iye owó ẹ̀kọ́ tó gaara.[7] Síwájú síi láìpẹ́, ìjà àti ìgbésùnmọ̀mí ti fa ìyípadà lábẹ́nú fún àwọn ènìyàn,ìbàjẹ́ ohun èlò ilé ẹ̀kọ́ àti mímú àwọn ọmọ lọ fún ìlòkulò.Jùbẹ́́ẹ̀lo,ọ̀pọ̀ ìpànìyàn láwùjọ látowọ́ àwọn kanranjọ́ngbọ́n agbésùnmoọ̀mi ́ní àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti sokùnfà pípọ̀ àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn ọmọ tó ń jìyà ìpalára látàrí ìlòkulò.[8][9]

Awon Itokasi

  1. Carter & Togunde 2008, p. 1.
  2. Kazeem, Aramide (2012). "Children's Work in Nigeria: Exploring the Implications of Gender, Urban–Rural Residence, and Household Socioeconomic Status". The Review of Black Political Economy 39 (2): 187–201. doi:10.1007/s12114-011-9126-y. 
  3. Bhalotra, Sonia. "Child labour in Africa" (PDF). OECD. Archived from the original (PDF) on April 13, 2022. Retrieved May 29, 2020. 
  4. Rain, David (1997). "The women of Kano: internalized stress and the conditions of reproduction, Northern Nigeria". GeoJournal 43 (2): 175–187. doi:10.1023/A:1006815632077. ISSN 0343-2521. JSTOR 41147132. 
  5. Audu, Bala; Geidam, Ado; Jarma, Hajara (2009). "Child labor and sexual assault among girls in Maiduguri, Nigeria". International Journal of Gynecology & Obstetrics 104 (1): 64–67. doi:10.1016/j.ijgo.2008.09.007. PMID 18954870. 
  6. Paediatric Association of Nigeria, PAN (2012-08-15). "Paediatric Association of Nigeria (PAN) recommended routine immunization schedule for Nigerian children". Nigerian Journal of Paediatrics 39 (4). doi:10.4314/njp.v39i4.1. ISSN 0302-4660. http://dx.doi.org/10.4314/njp.v39i4.1. 
  7. Paediatric Association of Nigeria, PAN (2012-08-15). "Paediatric Association of Nigeria (PAN) recommended routine immunization schedule for Nigerian children". Nigerian Journal of Paediatrics 39 (4). doi:10.4314/njp.v39i4.1. ISSN 0302-4660. http://dx.doi.org/10.4314/njp.v39i4.1. 
  8. "Address by the Permanent Secretary, Federal Ministry of Education on Behalf of Col. A.A. Ali, Federal Commissioner for Education, Nigeria". dx.doi.org. 1978-05-05. Retrieved 2021-11-08. 
  9. "Prevalence and predictors of child labour among junior public secondary school students in Enugu, Nigeria: a cross-sectional study". BMC Public Health 21 (1339). 2021. doi:10.1186/s12889-021-11429-w. PMC 8262090. PMID 34233655. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=8262090.  Àdàkọ:CC-notice