Henry Ford (July 30, 1863 – April 7, 1947) jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, onímọ̀ẹ̀rọ àti oníṣòwò ni ,óbẹ̀rè iṣẹ́ ṣíṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Ford ní 1896.
ó ṣètò bí òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan á ṣe máa ṣe páàtì kan lára ọkọ̀ èyí jẹ́ki ṣíṣe ọkọ̀ tuntun jáde lọ́pọ̀ yanturu àti ni ẹ̀dínwó túnbọ̀ rọrùn fun.ọ̀pọ̀ Àwọn iléiṣẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti àwọn ilé iṣẹ́ mìrán àn kárí ayé ríipé ìṣètò yí wúlò gan wọ́nsì bẹ̀rẹ̀ sí lòó. Nígbà tóyá ó pàdée Clara Bryant ẹni tóbá ṣègbeyàwó wọ́nbí ọmọ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ únjẹ́ Edsel, Bryant, Ford.
Henry kúrò nílé lọsí Detroit, Michigan láti dá iléiṣẹ́ ọkọ̀ayọ́kẹ́lẹ́ tiẹ̀ náà sílẹ̀.
Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀ Ilé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ford
Henry Ford dá iléiṣẹ́ tiẹ̀ náà sílẹ̀ ní 1903,[1] ọkọ̀ àkọ́kọ́ tóṣe jáde nílé iṣẹ́ nàn ni model T car wọ́n sì ta ọkọ̀ náà ní 23/07/1903 ó sì di ààrẹ iléiṣẹ́ nà ní 1906.
Ní 1908 Ó pinnu látiṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí onírúurú ènìyàn lèrà ìbáàjẹ̀ olówó tàbí tálákà nípàtàkì jùlọ Amẹ́ríkà[2]
àwọn ọkọ̀ tó ún ṣe kòwọ́nwó jù $850 ni Model T car kan nígbàyẹn èyí sì fa ìtẹ̀síwájú bá orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Láìnì Àpéjọ
Henry gbé ìṣètò láìnì àpéjọ jáde,ní 1913 ìṣètò yí jẹ́kí iṣẹ́ yá gan juti tẹ́lẹ̀ lọ,ó rọrùn fún òṣìṣ ẹ́ kọ̀ọ̀kan láti fi páàtì tóṣe sára ọkọ̀ tíwọnúnṣe lórí ẹ̀rọ bẹ́líìtì tó n yí (conveyor belt) láìsí ìdílọ́wọ́. Ní 1916 Henry tún já owó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ford wálẹ̀ sí $360 èyí túnbọ̀ mú ìtẹ̀síwájú bá Amẹ́ríkà [3]
Ojú Ìwòye Ẹ̀ Nípa Òṣèlú
Ogun àgbáyé kinni bàá nínújẹ́ gan óri gẹ́gẹ́bí ìfàkókòṣòfò bákan náà ógbàgbọ́ pé àwọn Júù ló fa ìṣòro àgbáyé.Nítorí èyí ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún (1919) ó ṣagbátẹrù ìwé ìròyìn kan tó n jẹ́ Òmìniraàmi ọ̀wọ́n (Dearborn Independent) ó ún gbé àpilẹ̀kọ kan jáde látìgbàdégbà to n dẹ́bi fún bí àwọn Júù ṣe n fa wàhálà bá aráyé àti bíwọn túnṣe n gbèrò ogun àgbáyé kejì.