Eko Hotels and Suites jẹ́ ilé ìtura onípele márún ní ìlú Èkó.[1][3][4][5]
Àwọn ilé ounjẹ mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ilé ọtí mẹ́jọ ni ó wà ní ilé ìtura yìí.[2]
Ìtàn nípa rẹ̀
Wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1977[6] bí Èkó Holiday Inn[7] atí wọ́n sì kọ́ọ sí Victoria Island, ó sì jẹ́ ilé ìtura tó tóbi jùlọ ní ìlú Èkó. Wọ́n yí orúkọ rẹ̀ sí Le Meridien Eko Hotel and Suites, Èkó. L'Hotel Eko Le Meridien jẹ́ ara ilé iṣẹ́ Chagoury Group.[8]
Kíkọ́ rẹ̀
Ilé ìtura yìí ní yàrá bíi 825[1][9] sí ilé alájà mẹ́rin tí ó tóbi, wọ́n kùú ní funfun, òkun wa ní iwájú rẹ̀ àti etí ọsà Kùrámọ̀.[4] Wọ́n kọ́ ilé yìí sí ẹ̀gbẹ́ agbègbè ọrọ̀ ajé Lagos Island: Victoria Island, (tí ó jẹ́ agbègbè ibi ọjà títà àti ibùgbé) ṣùgbọ́n ó jìnà sí agbègbè aláriwo. Ilé ìtura yìí wà lẹ́gbẹ́ omi bí omi òkun Kùrámọ̀. Ibi tí wọ́n kọ sí yìí maa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn ní ààǹfàní láti wo òkun àti àyìká tí ó jẹ́ kí wọ́n maa ń pèé níEnvironment of Aquatic Splendour.[3] Àwọn ohun ìgbàlódé tí ó wà ní ilé ìtura yìí maa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn láànfàní sí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńla.
Àwọn ayẹyẹ
Eko Hotels and Suites ní àyè tí ó tóbi fún àyẹyẹ tí ó sì tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[10][11] Àwọn ayẹyẹ tí wọ́n ti ṣe níbẹ̀ ni àjọ̀dún orin, ìṣàgbéjáde eré, ìṣàfihàn iṣẹ́ ọnà, ayẹyẹ ìgbeyàwó[12] àti ayẹyẹ bíi Africa Magic Viewers Choice Awards, Africa Movie Academy Awards, AGRIKEXPO, àti oríṣiríṣi ìṣàfihàn ọlọ́dọọdún bí Lagos Photo Festival. Wọ́n maa ń lo ibẹ̀ fún ayẹyẹ yìí tí ó sì lè gba àwọn ènìyàn bíi ẹgbẹ̀rú mẹ́fà.[4]