Olùrànlọ́wọ́ Ìǹspẹ́kítọ̀ Gbogbogbò ti ọlọ́pàá (fẹ̀hìntì) Dabo Aliyu CON mni psc jẹ́ Alákoso ìjọba ní ìpínlẹ̀ Anambra láti Oṣù kọkànlá sí Oṣù kejìlá ọdún 1993, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àbojútó ìpínlẹ̀ Yobe láti Oṣù kejìlá ọdún 1993 sí Oṣù kẹjọ ọdún 1996 ní àkókò ìjọba ológun ti General Sani Abacha. Ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Olùdárí NSO State House Annex nígbà kan, ó tún jẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Ìǹspẹ́kítọ̀ Gbogbogbò ti ọlọ́pàá ti agbègbè Zone 7 Abuja. A fún un ní àmì-ẹ̀yẹ lórí Ìdènà àwọn ìwà burúkú, ẹ̀bùn lórí Kọmísọ́nà ọlọ́pàá tí ó dára jùlọ nípasẹ̀ Olùyẹ̀wò Gbogbogbò ti ọlọ́pàá àtí ẹ̀bùn lórí iṣẹ́ ọlọ́pàá tó dára jùlọ ní Ìpínlẹ̀ Anambra. Ó ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Kaduna, ó jẹ́ Sardaunan Ruma àkọ́lé ní ìlú abínibí rẹ̀, Ruma.[1]
Àwọn Ìtọ́ka Sí