Child prostitution in Nigeria jẹ́ ọ̀nà ìgba fífi àwọn ọmọdé ṣiṣẹ aṣẹ́wó. Iṣẹ́ aṣẹ́wo ti di iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọ̀ọ̀jọ́ wọn. Kódà tọmọdé àti tàgbà ló ní ṣíṣe yíì gẹ́gẹ́ bí ohun to ń fún wọn ní jíjẹ àti mímu. Àmọ́ èyí kì í ṣe ọ̀nà tó dára. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọ̀nà kan ò wọjà. Tí ó mú èyí túmọ̀ sí wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ló wà tí ènìyàn lè fí wá jíjẹ àtì mímu. Ìṣe Aṣẹ́wo àwọn ọmọdé nílẹ̀ Nàìjíríà ní ó jẹ́ wá lógún ní iṣẹ́ yìí.[1]
Iṣẹ́ aṣẹ́wo
Iṣẹ́ yìí ní bíba jẹ́ndà kejì ní àṣepọ̀. Tí ó lè jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ fún ara rẹ̀ tàbí wí pé wọn lọ ẹ̀tàn àti ipá fún un làti lè bá ẹlòmíràn ní àṣepọ̀. Tí a bá sọ mímọ̀ọ́mọ̀ ọmọdé náà, a ma sọ wí pé ó ń ṣiṣẹ́ yìí fún owó ni. Ṣùgbọ́n tí a bá sọ ti ẹ̀tàn àti ipá, èyí lè túmọ̀ sí wí pé ọmọ tí wọ́n mú lọ sókè òkun àìtọ́ ni[2]
Ìtàn
Ní ọdún 2019, àjọ tí ń gbógun tí kíkó àwọn ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ sọ fún CNN wí pé ó tó ọ̀kẹ́(20,000) obìnrin tí wọ́n tí fì ẹ̀tan àbí ipá mú lọ sí orílé-èdè Mali. Àwọn àjọ yìí sọ fún CNN wí pé àwon ní ẹ̀rí tó dájú lórí ọ̀rọ̀ yii.[3]
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tí àwọn Àjọ̀ tó ń gbógun tí ìwà ìbàjé ṣe sọ, nípa ti wọn má mú àwọn obìnrin náà ní Nigeria, wọ́n sọ wí pé ìlú Malaysia ni àwọn tí má ṣíṣe pẹ̀lú owó tọ pọ̀ ṣùgbọ́n awọn ò mọ bí àwọn ṣe bá ara àwọn ni Málì.[4] Ní Málì yẹn ní àwọn ọdaran yii ti ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin yíì. Àwọn yòókù tí wọn ní kó ṣíṣe ní ilé ìtura ní Mali náà di títa lati mọ̀ wí pé wọ́n tí tá àwọn fún ilé ìtura náà. Ohun tó yẹ ka ṣe àkíyèsí rẹ̀ nínú wo pé obìnrin ló sáábà máa ń jẹ́ awon. Àwọn ohun tó ń fa èyí, ohun tó má dá sílẹ̀ àti ọ̀nà àbáyọ la ma mẹ́nubà nínu iṣẹ́ yìí.[5]
Àwọn okùnfà rẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wí pé kò sí nǹkan ni àwùjọ tí kò ní ohun tí ó hún fà á. Lára àwọn ohun tí ó fa Iṣẹ́-aṣẹ́wó ọmọdé ni: iṣẹ́, àwọn ọ̀rẹ́, Àìnímọ̀ nípa àwọn àrùn tí ó lè fà, Àdúgbo ẹni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ Aṣẹ́wo ní ọ̀nà mímú ọmọdé lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ ni a ma fẹ́ ẹ̀ mújútó nínu iṣẹ́ yìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé ni ò nímọ̀ nípa àwọn àrùn tí gbóògùn tí wọ́n ma kó tí àwọn bá ń ṣe Aṣẹ́wo àti wí pé tí ó bá jẹ́ mímú wọn lọ́nà àìtọ́ lọ sí ibòmíràn ni, èyí jẹ́ wí pé ipá lọ ma lò láti fi jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ Aṣẹ́wo yìí. Tí a bá wo ará àdúgbò àti àwọn ọ̀rẹ́, a ma ri wí pé àwọn méjèèjì yìí wà lára àwọn nǹkan tó máa bá ìhùwàsí àwọn ènìyàn lọ rè é. Kò sí ẹnì kankan tí a lè sọ wí pé àpẹẹrẹ àwọn méjèèjì ò hàn nínu ìhùwàsí rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ wí pé àwọn ọ̀rẹ́ àwọn ọmọdé yìí bá ń ṣe iṣẹ́ yìí, àyè wà wí pé àwọn náà má ṣe é.
Iṣẹ́ àti àìríṣẹ àwọn ọmọdé náà máa ń fà á. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni Èṣù ń bẹ̀wò.
Àwọn ohun tí ó máa ń dá sílẹ̀
Àrùn kògbóògùn jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn àrùn bí i HIV/AIDS àti àwọn àrùn mìíràn tí ó jẹ́ wí pé ènìyàn má á kó látara ìbáṣepọ̀. Àwọn àrùn yìí ò kògbóògùn tó túmọ̀ sí wí pé bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọdé yìí ṣe ma bá ara wọn láíláí.
Ó tún lè fa ìrònú ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sí fún àwọn ọmọdé. Bí àpẹẹrẹ tí ó bá jẹ́ ọmọdé tí wọ́n fi ẹ̀tan àti kíkọpá mú lọ sí ilẹ̀ mìíràn lọ́nà àìtọ́, èyí ma jẹ́ ìrònú ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sí fun lẹ́yìn tí ó bá rí àwọn ènìyàn gbà á lè. Kódà ó tún lè fa àbámọ̀ fún wọn lẹ́yìn tí wọn ba ti ko àwọn àrùn tán.
Àwọn ọ̀nà àbáyọ
ohun tí a nílò láti ṣe jù ni kí a kó àwọn ọmọdé ní àwọn ewu tó wà ní irú iṣẹ́ yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ní ò mọ àwọn ewu yìí. Tí a bá kọ́ wọn ní àwọn ewu yìí. A ma rí wí pé àwọn ọmọdé púpọ̀ tí ó ń ṣe iṣẹ́ yìí ma dáwọ́ duro lórí rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sọ tẹ́lẹ̀ wí pé ọwọ́ tó dá dilẹ̀ ni Èṣù bẹ̀wò, ó yẹ ka fi àwọn ọmọdé wa tàbí àwọn ọmọdé tí a bá mọ̀ ṣinú iṣẹ́. A ò lè ma dúró de ìjọba. Ọ̀míràn ni kí a kọ́ àwọn ọmọdé yìí nípa sùúrù. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní sùúrù ni baba ìwà. Sùúrù yìí nípa iṣẹ́ tì ó jẹ́ àwọn ọmọ ènìyàn ni. Ohun tí ó yẹ ka à ni wí pé ohun tó kúrò ma padà dùn.
Àwọn ìtọ́kasí
- ↑ Tade, Oludayo (2019-06-19). "Study shines light on how vulnerable children are trafficked in Nigeria". The Conversation. Retrieved 2022-03-30.
- ↑ Jenkins, John Philip (2021-08-31). "Definition, History, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2022-03-30.
- ↑ Obarayese, Sikiru (2021-11-29). "Undercover: Police, brothel owners make millions as child prostitution, sex trafficking reign in Osun". Daily Post Nigeria. Retrieved 2022-03-30.
- ↑ Oyafunke-Omoniyi, Comfort; Adewusi, Adedeji (2022-03-17). Serpa, Sandro. ed. "Child prostitution in Ibadan, Nigeria: Causes, perceived consequences and coping strategies". Cogent Social Sciences (Informa UK Limited) 8 (1). doi:10.1080/23311886.2022.2047260. ISSN 2331-1886.
- ↑ Ovuorie, Tobore; Onadipe, Yemisi (2019-10-31). "Locked Out – Nigeria’s Trafficked Children Have Never been to School". ReliefWeb. Retrieved 2022-03-30.