Bí Ayé bá tún dá'adé ("When Life Is Good Again") jẹ́ orin tí arábìnrin akọrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dolly Parton, tí ó tún jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ. Wọ́n gbé orin yìí jáde lábẹ́ ilé-iṣẹ́ ìgbórin-jáde Butterfly Records ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2020. Dolly Parton ni ó ṣe àpilẹ̀kọ orin yí pẹ́lú ìrànlọ́wọ́ arákùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kent Wells, tí ó tún gbé àwo orin náà jàde.
Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀
Ṣáájú kí wọ́n tó gbé orin yí jáde, Parton ti agbékalẹ̀ ètò sísọ ìtàn àgbọ́sùn kan fún àwọn ọmọdé lórí ẹ̀rọ ayélujára tí ó le àkòrí rẹ̀ ní Goodnight with Dolly fún odidi ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá. Àwọn ọlọ́kan-ò-jọkan ìwé tí ó ṣamúlò ni ó ṣe àfàyọ.rẹ̀ láti inú àká ìwé tí tún ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọdé láti lè jẹ́ kí ìmọ̀ òun ẹ̀kọ́ wọn ó n
Kún kẹ́kẹ́ si. Ó tún gbé owó tùùlù tuuulu kan tí iye rẹ̀ jẹ́ mílíọ́nù kan owó Dọ́la fún ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn ti fásitì ti Vanderbilt University Medical Center láti lè kún wọn lápá lórí ìwádí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí oògùn àjẹsára fún àrùn. coranavirus.[1] Wọ́n ṣàfihàn orin yí fún ìgba akọ́kọ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ Entertainment Weekly ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Karùún ọdún 2020, wọ́n sì gbe orin náà sí orí Ìtàkùn ayélujára fún gbígbọ́ àwọn ènìyàn.[2]
Ìhun orin náà
Dolly Parton ati Krnt Wells ni ó hun orin "When Life Is Good Again". Ó jẹ́ orin country pop tí ó sùn gùn tó ìṣẹ́jú mẹ́rin gbáko. Orin náà dá lórí ìgbésí ayé lẹ́yìn ajàkálẹ̀ àrùn coronavirus (COVID-19) pandemic. Ó tún sọ wípé òun yóò sọ nípa ìbásepọ̀ àti ìrírí ayé òun nínú ayé, pàá pàá jùlọ kí àwọn ènìyàn le ní amọ̀dájú wípé ayé ṣì ń bọ̀ wá di gbẹdẹmukẹ fún wọn lẹ́yìn gbogbo làá làá ajàkálẹ̀ arùn yí.
Àríwísí àwọn ènìyàn
Orin yí ti kọjá lárí agbọ́nrin oríṣiríṣi àríwísí tó dára lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn láti ìgbà tí wọ́n ti gbe jáde.[3][1][4] Arábìnrin Melinda Lorge tí ó kọ Taste of Country ti ṣàpèjúwe orin yí gẹ́gẹ́ bí "ìgbéga rere".[1]
Yíya fídíò orin yí
Ọ̀gbẹ́ni Steve Summers ló darí yíya àwòrán fídíò náà, wọ́n sì ṣe àfihàn fídíò náà ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Karùún ọdún 2020. Lásìkò tí wọ́n ṣàfihàn fídíò yí, oríṣiríṣi ìbéèrè ni àwọn ènìyàn pàá pàá jùlọ àwọn oníwé ìròyìn béèrè lọ́wọ́ Dolly Parton nípa orin náà.
Atẹ
Àdàkọ:Singlechart
Chart (2020)
|
Peak position
|
US Country Digital Song Sales (Billboard)[5]
|
11
|
Bí wọ́n ṣe fi àwòrán orin náà léde
Country
|
Date
|
Format
|
Label
|
Various
|
May 28, 2020
|
|
Butterfly
|
Àwọn Ìtọ́kasí