Akoko North-East jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní Ìpínlẹ̀ Òndó, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Olú-ìlú náà wà ní Ìkàrẹ́-Akóko. Ìkàré ní ìlú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí ń ṣe:[2] Okela, Okorun, Eshe, Odo, Ilepa, Okoja, Iku, Odeyare, Odoruwa, Okeruwa, Iyame, Igbede, Oyinmo, Ishakunmi, àti Ekan.
Ìwọ̀n agbègbè náà lọ bí i 372 km2, iye àwọn ènìyàn tó sì wà níbẹ̀ lásìkò ìka-orí ti ọdún 2006 jẹ́175,409.
Nọ́ḿbà ìfìwéránṣẹ́ ìlú náà ni 342.[3]
Àwọn ìtọ́kasí