Òṣogbo jẹ́ ìlú ńlá kan ní ìpílẹ̀ Ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bákan náà ni ó jẹ́ olú ìlú fún ìpínlẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ọ̀gbẹ́ni Adémó̩lá Adélékè ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lọ́wọ́lọ́wọ́. Òṣogbo di olú ìlú fụ́n Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọdun 1991.[1] Bákan náà ni ó tún jẹ́ olú ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ fún ìlú Òṣogbo, tí ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà sì wà ní Òke Báálẹ̀, nígbà tí ìjọba ìbílẹ̀ Ọlọ́rundá ń ṣojú agbègbè Ìgbóǹnà nílú Òṣogbo.[1][2]